Select a language and narrator voice before playback.
Nibẹ ni wọn ti sọ pe igbesẹ Gomina Ademola Adeleke lati dawọ gbogbo iṣẹ NURTW nipinlẹ Osun ko ba ofin ati ilana ti wọn fi da ẹgbẹ wọn silẹ mu.
Aarọ Ọjọru, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni awọn mọlẹbi Olu Jacobs kede ipapoda rẹ.
Aremu ni oun gbagbọ oun ati awọn iyawo oun merin jọ n lo arísìkí ara wọn ti nnkan ti rọrun fun wọn titi di asiko yii.
Nyesom Wike wa sọ pe Aarẹ Bola Tinubu loun ba da owo pọ kii ṣe awọn gomina APC.
Nibi ikọlu to waye ni garaaji Mayfair naa ni wọn ti yinbọn pa ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ naa, Olalekan Oyeymi, ẹni tọpọ mọ si Emir Ajagungbade.
Aondongu ọ pe ọga ọlọpaa ẹkun ọhun lọ gba nnkan niluu Makurdi , ati pe asiko toun pẹlu ikọ akọwọrin rẹ n pada lọ si ibudo wọn, ni awọn agbebọn naa da wọn lọna.
Ijọba ipinlẹ naa tun ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii to peye lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun pẹlu ikede pe mọṣalaṣi naa ti di ibi ti wọn ti wuwa ọdaran.
Minisita fọrọ awọn ọlọpaa ni South Africa, Firoz Cachalia fi aidunu rẹ lori ipaniyan naa han, to si ba ẹbi awọn eeyan to ti padanu ẹmi wọn kẹdun.
Awọn afurasi marun-un naa ni wọn mu lasiko ti wọn ri wọn ninu aṣọ ọmọ ologun ninu igbo Ọba to wa ni agbegbe ọhun.
Ofoyeju sọ pe igbo ti awọn eeyan n gbin, lo ti n rọpo awọn ohun jijẹ to yẹ ki wọn maa fi oko ati igbo gbin bayii, leyi to si le ṣe akoba pupo fun alaafia ilu.
Gẹgẹ bii JAMB ṣe sọ, ẹredi atunṣe naa ko ṣẹyin ewu to le de ba awọn akẹkọọ ti wọn ba rinrinajo lọ kọ idanwo naa ni afẹmọju.
Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni orilẹ ede naa sọ pe eeyan mejila lo ti lugbadi aarun naa lopin ọsẹ lẹyin ti wọn je ẹran igbo kan ni agbegbe Munyamadzi River.
Ninu orukọ naa ti INEC gbe jade, eyi ti akọwe rẹ, Rose Oriaran-Anthony, buwọ lu lọjọ Abamẹta to kọja niluu Abuja, lo ti fidi rẹ mulẹ pe awọn oludije naa ni ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun fi ranṣẹ si wọn.
Eeyan 107 ni wọn ti doola ninu ijamba ọhun bayii lẹyin ti ọkọ oju omi Virgo Transport8 naa danu.
Bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni Elliot dalẹ Gbajabiamila, ẹkọ fi oju mimu han pe Elliot ti tẹ aṣọ agba mọlẹ ninu oṣelu ipinlẹ Eko lo ṣe n bẹbẹ lori ekun rẹ.
Agba sọrọsọrọ naa sọ pe bi awọn araalu ba ṣetan lati yan oun si ipo, ko sẹni to le da oun duro.
Ọwọ ọlọpaa tun tẹ awọn afurasi mẹrinla mii to n ta paraga lagbagbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Latigba ti iroyin ibanujẹ ọhun ti jade, ni ọpọ awọn to mọ ọkunrin naa ti bẹrẹ sii kẹdun, ti awọn miran si n barajẹ.
Iroyin ni Ajagungbade atawọn eeyan ti wọn jọ wa ni garaaji ni ija bẹ silẹ laaarin wọn, ti wọn yinbọn fun-un ṣugbọn ti idi ti wọn fi yinbọn pa ko i tii ye ẹnikẹni titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ.